Judges 13:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Bí o bá dá mi dúró, n kò ní jẹ ninu oúnjẹ rẹ, ṣugbọn tí o bá fẹ́ tọ́jú ohun tí o fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, OLUWA ni kí o rú u sí.” Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLUWA ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Angeli OLUWA na si wi fun Manoa pe, Bi iwọ tilẹ da mi duro, emi ki yio jẹ ninu àkara rẹ: bi iwọ o ba si ru ẹbọ sisun kan, OLUWA ni ki iwọ ki o ru u si. Nitori Manoa kò mọ̀ pe angeli OLUWA ni iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ańgẹ́lì OLÚWA náà dá Mánóà lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, Èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹyin yóò pèṣè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèṣè ọrẹ ẹbọ ṣíṣun, kí ẹ sì fi rúbọ sí OLÚWA.” (Mánóà kò mọ̀ pé ańgẹ́lì OLÚWA ní i ṣe.)