Judges 13:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọwọ́ iná ẹbọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè láti orí pẹpẹ, angẹli OLUWA náà bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ ninu ọwọ́ iná orí pẹpẹ náà, bí Manoa ati iyawo rẹ̀ ti ń wò ó. Wọ́n bá dojú wọn bolẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ti ọwọ́-iná na nlọ soke ọrun lati ibi-pẹpẹ na wá, angeli OLUWA na si gòke ninu ọwọ́-iná ti o ti ibi-pẹpẹ jade wá. Manoa ati aya rẹ̀ si nwò o; nwọn si dojubolẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, ańgẹ́lì OLÚWA gòkè re ọ̀run láàárin ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Mánóà àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojú bolẹ̀.