Judges 13:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn iyawo rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Bí ó bá ṣe pé OLUWA fẹ́ pa wá ni, kò ní gba ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ tí a rú sí i lọ́wọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni kò ní fi nǹkan wọnyi hàn wá, tabi kí ó sọ wọ́n fún wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Aya rẹ̀ si wi fun u pe, Ibaṣepe o wù OLUWA lati pa wa, on kì ba ti gbà ẹbọ sisun ati ẹbọ ohunjijẹ li ọwọ́ wa, bẹ̃li on kì ba ti fi gbogbo nkan wọnyi hàn wa, bẹ̃li on kì ba ti sọ̀rọ irú nkan wọnyi fun wa li akokò yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí OLÚWA bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ọrẹ ṣísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.”