Judges 13:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan. Abẹ kò gbọdọ̀ kan orí rẹ̀, nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀; òun ni yóo sì gba Israẹli sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; ki abẹ ki o má ṣe kàn a lori: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá: on o bẹ̀rẹsi gbà Israeli li ọwọ́ awọn Filistini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má se fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Násírì (ẹni ìyàsọ́tọ̀) Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Fílístínì.”