Judges 13:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Obinrin náà bá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Eniyan Ọlọrun kan tọ̀ mí wá, ìrísí rẹ̀ jọ ìrísí angẹli Ọlọrun. Ó bani lẹ́rù gidigidi. N kò bèèrè ibi tí ó ti wá, kò sì sọ orúkọ ara rẹ̀ fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana obinrin na wá, o si rò fun ọkọ rẹ̀, wipe, Enia Ọlọrun kan wá sọdọ mi, irí rẹ̀ si dabi irí angeli Ọlọrun, o ní ẹ̀ru gidigidi; ṣugbọn emi kò bilère ibiti o ti wá, bẹ̃li on kò si sọ orukọ rẹ̀ fun mi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Èniyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ ańgẹ́lì Ọlọ́run, ó bà ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi.