Judges 13:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ó wí fún mi pé, n óo lóyún, n óo sì bí ọmọkunrin kan. Ó ní n kò gbọdọ̀ mu ọtí waini, tabi ọtí líle. N kò sì gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́; nítorí pé, Nasiri Ọlọrun ni ọmọ náà yóo jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí yóo fi jáde láyé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn on sọ fun mi pe, Kiyesi i, iwọ o lóyun, iwọ o si bi ọmọkunrin kan; nitorina má ṣe mu ọti-waini tabi ọti lile, bẹ̃ni ki o má ṣe jẹ ohun aimọ́ kan: nitori Nasiri Ọlọrun li ọmọ na o jẹ́ lati inu wá titi di ọjọ́ ikú rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má se jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Násírì Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ”