Judges 13:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Manoa bá gbadura sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí iranṣẹ rẹ tí o rán sí wa tún pada wá, kí ó wá kọ́ wa bí a óo ṣe máa tọ́jú ọmọkunrin tí a óo bí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Manoa bẹ̀ OLUWA, o si wipe, OLUWA, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki enia Ọlọrun, ti iwọ rán tun tọ̀ wa wá, ki o le kọ́ wa li ohun ti awa o ṣe si ọmọ na ti a o bi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Mánóà gbàdúrà sí OLÚWA wí pé, “Háà OLÚWA, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”