Judges 14:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fun yín, bí ẹ bá lè túmọ̀ àlọ́ náà láàrin ọjọ́ meje tí a ó fi se àsè igbeyawo yìí, n óo fun yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù funfun ati ọgbọ̀n aṣọ àríyá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki npa alọ́ kan fun nyin: bi ẹnyin ba le já a fun mi titi ijọ́ meje àse yi, ti ẹnyin ba si mọ̀ ọ, njẹ emi o fun nyin li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúsónì sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fún un yín, bí ẹ̀yin bá lè fún mi ní ìtúmọ̀ rẹ̀ láàárin ọjọ́ méje àsè yìí, tàbí ṣe àwárí àdìtú náà èmi yóò fún un yín ní ọgbọ̀n (30) aṣọ tí a fi òwú ọ̀gbọ̀ hun, àti ọgbọ̀n (30) ìpàrọ̀ aṣọ ìyàwó.