Judges 14:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹrin, wọ́n wá bẹ iyawo Samsoni pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún wa, láì ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sun ìwọ ati ilé baba rẹ níná. Àbí pípè tí o pè wá wá sí ibí yìí, o fẹ́ sọ wá di aláìní ni?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn si wi fun obinrin Samsoni pe, Tàn ọkọ rẹ, ki o le já alọ́ na fun wa, ki awa ki o má ba fi iná sun iwọ ati ile baba rẹ: ẹnyin pè wa ki ẹnyin ki o le gbà ohun-iní wa ni? bẹ̃ ha kọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n wí fún ìyàwó Sámúsónì, pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó lè ṣe àlàyé àlọ́ náà fún wa, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò sun ìwọ àti ìdílé baba rẹ̀ ní iná. Tàbí ṣe o pè wá sí ibi àsè yìí láti sọ wá di òtòsì tàbí kó wa lẹ́rú ni?”