Judges 14:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iyawo Samsoni bá bẹ̀rẹ̀ sì sọkún níwájú rẹ̀, ó ní, “O kò fẹ́ràn mi rárá, irọ́ ni ò ń pa fún mi. O kórìíra mi; nítorí pé o pa àlọ́ fún àwọn ará ìlú mi, o kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.” Samsoni bá dá a lóhùn pé, “Ohun tí n kò sọ fún baba tabi ìyá mi, n óo ti ṣe wá sọ fún ọ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Obinrin Samsoni si sọkun niwaju rẹ̀, o si wipe, Iwọ korira mi ni, iwọ kò si fẹràn mi: iwọ pa alọ́ kan fun awọn ọmọ enia mi, iwọ kò si já a fun mi. On si wi fun u pe, Kiyesi i, emi kò já a fun baba ati iya mi, emi o ha já a fun ọ bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ìyàwó Sámúsónì ṣubú lé e láyà, ó sì sunkún ní iwájú rẹ̀ pé, “O kórìíra mi! o kò sì ní ìfẹ́ mi nítòótọ́, o pàlọ́ fún àwọn ènìyàn mi, ìwọ kò sì sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún mi.” “Èmi kò tí ì ṣe àlàyé rẹ̀ fún baba àti ìyá mi, báwo ni èmi ó ṣe sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”