Judges 14:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ni iyawo rẹ̀ bá tún bẹ̀rẹ̀ sí sọkún títí gbogbo ọjọ́ mejeeje tí wọ́n fi se àsè náà. Ṣugbọn nígbà tí ó di ọjọ́ keje, Samsoni sọ fún un, nítorí pé ó fún un lọ́rùn gidigidi. Obinrin náà bá lọ sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ará ìlú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si sọkun niwaju rẹ̀ titi ijọ́ meje ti àse na gbà: O si ṣe ni ijọ́ keje, o si já a fun u, nitoripe on ṣe e li aisimi pupọ̀, on si já alọ́ na fun awọn ọmọ enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún gbogbo ọjọ́ méje tí wọ́n fi ṣe àsè náà ni ó fi sunkún, nítorí náà ní ọjọ́ keje ó sọ ìtúmọ̀ rẹ̀ fún un nítorí pé ó yọ ọ́ lẹ́nu ní ojoojúmọ́. Òun náà sì sọ ìtúmọ̀ àlọ́ náà fún àwọn ènìyàn rẹ̀