Judges 14:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó di ọjọ́ keje, kí ó tó di pé oòrùn wọ̀, àwọn ará ìlú rẹ̀ náà wá sọ ìtumọ̀ àlọ́ Samsoni wí pé, “Kí ló dùn ju oyin lọ; kí ló lágbára ju kinniun lọ?” Ó ní, “Bí kò bá jẹ́ pé mààlúù mi ni ẹ fi tulẹ̀, ẹ kì bá tí lè túmọ̀ àlọ́ mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin ilunla na si wi fun u ni ijọ́ keje ki õrùn ki o to wọ̀ pe, Kili o dùn jù oyin lọ? kili o si lí agbara jù kiniun lọ? On si wi fun wọn pe, Ibaṣepe ẹnyin kò fi ẹgbọrọ abo-malu mi tulẹ, ẹnyin kì ba ti mọ̀ alọ́ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ó tó di àṣálẹ́ ọjọ́ keje àwọn ọkùnrin ìlú náà sọ fún un pé, “Kí ni ó dùn ju oyin lọ? Kí ni ó sì lágbára ju kìnìún lọ?” Sámúsónì dá wọn lóhùn pé, “Bí kì í bá ṣe pé ẹ fi ọ̀dọ́ màlúù mi kọ ilẹ̀, ẹ̀yin kò bá tí mọ ìtumọ̀ sí àlọ́ mi.”