Judges 14:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé e tagbára tagbára, ó lọ sí Aṣikeloni, ó sì pa ọgbọ̀n ninu àwọn ọkunrin ìlú náà, ó kó ìkógun wọn, ó sì fún àwọn tí wọ́n túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ ní aṣọ àríyá wọn; ó bá pada lọ sí ilé baba rẹ̀ pẹlu ibinu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si sọkalẹ lọ si Aṣkeloni, o si pa ọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn, o si kò ẹrù wọn, o si fi ìparọ aṣọ fun awọn ti o já alọ́ na. Ibinu rẹ̀ si rú, on si gòke lọ si ile baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn èyí, ẹ̀mí OLÚWA bà lé e pẹ̀lú agbára. Ó lọ sí Ásíkélónì, ó pa ọgbọ̀n (30) nínú àwọn ọkùnrin wọn, ó gba àwọn ohun ìní wọn, ó sì fi àwọn aṣọ wọn fún àwọn tí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà. Ó sì padà sí ilé baba rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú ríru.