Judges 14:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Baba ati ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Ṣé kò sí obinrin mọ́ ninu gbogbo àwọn ìbátan rẹ tabi láàrin gbogbo àwọn eniyan wa ni o fi níláti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ará Filistia aláìkọlà ni?” Samsoni bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Ẹ ṣá fẹ́ ẹ fún mi nítorí ó wù mí pupọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni baba on iya rẹ̀ wi fun u pe, Kò sí obinrin kan ninu awọn ọmọbinrin awọn arakunrin rẹ, tabi ninu gbogbo awọn enia mi, ti iwọ fi nlọ ní obinrin ninu awọn alaikọlà Filistini? Samsoni si wi fun baba rẹ̀ pe, Fẹ́ ẹ fun mi; nitoripe o wù mi gidigidi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Baba àti ìyá rẹ̀ dáhùn pé, ṣé kò sí obìnrin tí ó dára tí ó sì tẹ́ ọ lọ́rùn ní àárin àwọn ìbátan rẹ, tàbí láàárin gbogbo àwọn ènìyàn wa? Ṣé ó di túlàsì fún ọ láti lọ sí àárin àwọn Fílístínì aláìkọlà kí o tó fẹ́ ìyàwó? Ṣùgbọ́n Sámúsónì wí fún baba rẹ̀ pé, “Fẹ́ ẹ fún mi torí pé inú mi yọ́ síi púpọ̀ púpọ̀.”