Judges 14:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn baba ati ìyá rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ní ọwọ́ OLUWA ninu, nítorí pé OLUWA ti ń wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Filistia nítorí pé, àwọn ni wọ́n ń mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àkókò yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn baba ati iya rẹ̀ kò mọ̀ pe ati ọwọ́ OLUWA wá ni, nitoripe on nwá ọ̀na lati bá awọn Filistini jà. Nitoripe li akokò na awọn Filistini li alaṣẹ ni Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
(Àwọn òbí rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀dọ̀ OLÚWA ni nǹkan yìí ti wá, ẹni tí ń wá ọ̀nà àti bá Fílístínì jà; nítorí àwọn ni ń ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní àkókò náà.)