Judges 14:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀mí OLUWA bà lé e, ó sì fún un ní agbára ńlá, ó bá fa kinniun náà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ìgbà tí eniyan ya ọmọ ewúrẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò mú ohunkohun lọ́wọ́. Ṣugbọn kò sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún baba tabi ìyá rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si fà a ya bi iba ti fà ọmọ-ewurẹ ya, bẹ̃ni kò sí nkan li ọwọ́ rẹ̀: on kò si sọ fun baba tabi iya rẹ̀ li ohun ti o ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀mí OLÚWA sì bà lé e pẹ̀lú agbára tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi fa kìnnìún náà ya pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lásán bí ẹní ya ọmọ ewúrẹ́, ṣùgbọ́n òun kò sọ ohun tí ó ṣe fún baba tàbí ìyá rẹ̀.