Judges 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá yọ́ ninu afárá oyin náà sí ọwọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lá a bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó bá baba ati ìyá rẹ̀, ó fún wọn lá ninu rẹ̀; ṣugbọn kò sọ fún wọn pé ara òkú kinniun ni òun ti rẹ́ afárá oyin náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si bù ninu rẹ̀ si ọwọ́ rẹ̀, o si njẹ ẹ li ajẹrìn, titi o si fi dé ọdọ baba ati iya rẹ̀, o si fi fun wọn, nwọn si jẹ: ṣugbọn on kò sọ fun wọn pe ninu okú kiniun li on ti mú oyin na wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ó fi ọwọ́ ha jáde, ó sì ń jẹ ẹ́ bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, ó fún wọn ní díẹ̀, àwọn náà sì jẹ, ṣùgbọ́n kò sọ fún wọn pé ara òkú kìnnìún ni òun ti rí oyin náà.