Judges 15:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè ọkà, Samsoni mú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó lọ bẹ iyawo rẹ̀ wò. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó ní, “Mo fẹ́ wọlé lọ bá iyawo mi ninu yàrá.” Ṣugbọn baba iyawo rẹ̀ kò jẹ́ kí ó wọlé lọ bá a.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O SI ṣe lẹhin ìgba diẹ, li akokò ikore alikama, Samsoni mú ọmọ ewurẹ kan lọ bẹ̀ aya rẹ̀ wò; on si wipe, Emi o wọle tọ̀ aya mi lọ ni iyẹwu. Ṣugbọn baba obinrin rẹ̀ kò jẹ ki o wọle.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè jéró Sámúsónì mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láàyè láti wọlé.