Judges 15:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹgbẹẹdogun (3,000) ọkunrin Juda lọ bá Samsoni ní ibi ihò àpáta tí ó wà ní Etamu, wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé àwọn ará Filistia ni wọ́n ń ṣe àkóso wa ni? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Oró tí wọ́n dá mi ni mo dá wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li ẹgbẹdogun ọkunrin Juda sọkalẹ lọ si palapala apata Etamu, nwọn si wi fun Samsoni, pe, Iwọ kò mọ̀ pe awọn Filistini li alaṣẹ lori wa? kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? On si wi fun wọn pe, Gẹgẹ bi nwọn ti ṣe si mi, bẹ̃li emi ṣe si wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) ọkùnrin láti Júdà sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Étamù, wọ́n sì sọ fún Sámúsónì pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Fílístínì ní ń ṣe alákóṣo lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?” Òun sì dáhùn pé, “Ohun tí wọ́n ṣe sí mi ni èmi náà ṣe sí wọn.”