Judges 15:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn pé, “A wá láti dì ọ́ tọwọ́ tẹsẹ̀ kí á sì gbé ọ lọ fún àwọn ará Filistia ni.” Samsoni dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ búra fún mi pé ẹ̀yin tìkara yín kò ní pa mí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun u pe, Awa sọkalẹ wá lati dè ọ, ki awa ki o le fi ọ lé awọn Filistini lọwọ. Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ bura fun mi, pe ẹnyin tikara nyin ki yio pa mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wí pé, “Àwa wá láti dè ọ́, kí a sì fi ọ́ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́.” Sámúsónì wí pé, “Ẹ búra fún mi pé, ẹ̀yin kì yóò fúnra yín pa mí.”