Judges 15:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá, àwa óo dì ọ́, a óo sì gbé ọ lé wọn lọ́wọ́ ni, a kò ní pa ọ́ rárá.” Wọ́n bá mú okùn titun meji, wọ́n fi dì í, wọ́n sì gbé e jáde láti inú ihò àpáta náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun u pe, Rárá o; didè li awa o dè ọ, a o si fi ọ lé wọn lọwọ: ṣugbọn niti pipa awa ki yio pa ọ. Nwọn si fi okùn titun meji dè e, nwọn si mú u gòke lati ibi apata na wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwá gbà,” ni ìdáhùn wọn. “Àwa yóò kàn dè ọ́, awa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́.” Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn túntún méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà.