Judges 15:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó dé Lehi, àwọn Filistia wá hó pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Samsoni tagbára tagbára, okùn tí wọ́n fi dè é sì já bí ìgbà tí iná ràn mọ́ fọ́nrán òwú. Gbogbo ìdè tí wọ́n fi dè é já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o dé Lehi, awọn Filistini hó bò o: ẹmi OLUWA si bà lé e, okùn ti o si wà li apa rẹ̀ si wa dabi okùn-ọ̀gbọ ti o ti jóna, ìde rẹ̀ si tú kuro li ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti sún mọ́ Léhì, àwọn Fílístínì ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí OLÚWA bà lé e pẹ̀lú agbára. Àwọn okùn ọwọ́ rẹ̀ dàbí òwú tí ó jóná, ìdè ọwọ́ rẹ̀ já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.