Judges 15:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Òùngbẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ ẹ́ gidigidi, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Ìwọ ni o ran èmi iranṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti ṣẹgun lónìí, ṣugbọn ṣé òùngbẹ ni yóo wá gbẹ mí pa, tí n óo fi bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà wọnyi?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ongbẹ si ngbẹ ẹ gidigidi, o si kepè OLUWA, wipe, Iwọ ti fi ìgbala nla yi lé ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ: nisisiyi emi o kú nitori ongbẹ, emi o si bọ́ si ọwọ́ awọn alaikọlà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe OLÚWA, wí pé, “Ìwọ ti fún ìránṣẹ́ ní ìṣẹ́gun tí ó tóbi yìí. Ṣé èmi yóò ha kú pẹ̀lú òǹgbẹ, kí èmi sì ṣubú sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà ènìyàn?”