Judges 15:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun bá la ibi ọ̀gbun kan tí ó wà ní Lehi, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti inú ọ̀gbun náà. Lẹ́yìn tí ó mu omi tán, ojú rẹ̀ wálẹ̀, nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Enhakore. Enhakore yìí sì wà ní Lehi títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Ọlọrun si là ibi kòto kan ti o wà ni Lehi, nibẹ̀ li omi si sun jade; nigbati on si mu u tán ẹmi rẹ̀ si tun pada, o si sọjí: nitorina ni a ṣe pè orukọ ibẹ̀ na ni Eni-hakkore, ti o wà ni Lehi, titi o fi di oni-oloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ọlọ́run la kòtò ìṣun omi tí ó wà ní Léhì, omi sì tú jáde láti inú rẹ̀. Nígbà tí Sámúsónì mú mi tan, agbára rẹ̀ sì padà, ọkàn sì sọjí, fún ìdí èyí wọ́n pe ìṣun omi náà ni. Ẹni Hákkò rẹ (oríṣun ẹni tí ó pe Ọlọ́run) èyí tí ó sì wà ní Léhì di òní.