Judges 15:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ṣáná sí àwọn ìtùfù náà, ó sì tú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sílẹ̀ ninu oko ọkà àwọn ará Filistia. Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yìí bá tan iná ran gbogbo ìtí ọkà ati àwọn ọkà tí ó wà ní òòró ati gbogbo ọgbà olifi wọn; gbogbo wọn sì jóná ráúráú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si ti fi iná si ètufu na, o jọwọ wọn lọ sinu oko-ọkà awọn Filistini, o si kun ati eyiti a dì ni ití, ati eyiti o wà li oró, ati ọgbà-olifi pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó fi iná ran àwọn ètúfù tí ó so náà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ sínú àwọn oko ọkà àwọn Fílístínì. Ó jó àwọn pòpóòrò ọkà tí ó dúró àti àwọn tí a dì ní ìtí, ìtí, pẹ̀lú àwọn oko àjàrà àti ólífì.