Judges 15:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ará Filistia bá bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè pé, “Ta ni ó dán irú èyí wò?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni, ọkọ ọmọ ará Timna ni; nítorí pé àna rẹ̀ fi iyawo rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Àwọn ará Filistia bá lọ dáná sun iyawo náà ati baba rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn Filistini wipe, Tani ṣe eyi? Nwọn si dahùn pe, Samsoni, ana ara Timna ni, nitoriti o gbà obinrin rẹ̀, o si fi i fun ẹgbẹ rẹ̀. Awọn Filistini si gòke wá, nwọn si fi iná sun obinrin na ati baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn Fílístínì béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Sámúsónì ará Tímínà ni, nítorí o gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Nítorí náà àwọn Fílístínì lọ wọ́n sì ṣun obìnrin náà àti baba rẹ̀.