Judges 16:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Delila bá mú okùn titun, ó fi dè é, ó sì wí fún un pé, “Samsoni, àwọn ará Filistia dé!” Àwọn tí wọ́n sápamọ́ sì wà ninu yàrá inú. Ṣugbọn Samsoni fa okùn náà já bí ẹni pé fọ́nrán òwú kan ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Delila mú okùn titun, o si fi dè e, o si wi fun u pe, Awọn Filistini dé, Samsoni. Awọn ti o lumọ́ dè e wà ninu yará. On si já wọn kuro li apa rẹ̀ bi owu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dẹ̀lílà sì mú àwọn okùn túntún, ó fi wọ́n dì í. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Fílístínì ti fi ara pamọ́ sínú yàrá, òun kígbe sí i pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ,” òun sì já okùn náà kúrò ní ọwọ́ rẹ̀ bí òwú.