Judges 16:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Delila rí i pé ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ palẹ̀ fún òun, ó ranṣẹ pe àwọn ọba Filistini, ó ní, “Ẹ tún wá lẹ́ẹ̀kan sí i, nítorí pé ó ti sọ gbogbo inú rẹ̀ fún mi.” Àwọn ọba Filistini maraarun bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n mú owó náà lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Delila ri pe, o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun u, o si ranṣẹ pè awọn ijoye Filistini, wipe, Ẹ gòke wá lẹ̃kan yi, nitoriti o sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fun mi. Nigbana li awọn ijoye Filistini wá sọdọ rẹ̀, nwọn si mú owo li ọwọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Dẹ̀lílà ríi pé ó ti sọ ohun gbogbo fún òun tan, Dẹ̀lílà ránṣẹ́ sí àwọn ìjòyè Fílístínì pé, “Ẹ wá lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ti sọ ohun gbogbo fún mi.” Torí náà àwọn olóyè Fílístínì padà, wọ́n sì mú owó ìpinnu náà lọ́wọ́.