Judges 16:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn kan bá lọ sọ fún àwọn ará Gasa pé Samsoni wà níbẹ̀. Wọ́n yí ilé náà po, wọ́n sì ba dè é níbi ẹnu ọ̀nà bodè ìlú ní gbogbo òru ọjọ́ náà. Wọ́n dákẹ́ rọ́rọ́, wọ́n ní, “Ẹ jẹ́ kí á dúró títí di ìdájí kí á tó pa á.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ara Gasa si gbọ́ pe, Samsoni wá si ihin. Nwọn si yi i ká, nwọn lùmọ́ ni gbogbo oru na li ẹnu-bode ilu na, nwọn si dakẹ jẹ ni gbogbo oru na, wipe, Li owurọ̀ nigbati ilẹ ba mọ́, li awa a pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Gásà sì gbọ́ wí pé, “Sámúsónì wà níbí.” Wọ́n sì yí agbégbé náà ká, wọ́n ń ṣọ́ ọ ní gbogbo òru náà ní ẹnu bodè ìlú náà. Wọn kò mira ní gbogbo òrú náà pé ní “àfẹ̀mọ́júmọ́ àwa yóò pa á”