Judges 16:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó wí fún un pé, “Samsoni! Àwọn ará Filistia ti dé.” Samsoni bá jí láti ojú oorun, ó ní, “N óo lọ bí mo ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, n óo sì gba ara mi lọ́wọ́ wọn.” Kò mọ̀ pé OLUWA ti fi òun sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wipe, Awọn Filistini dé, Samsoni. O si jí kuro li oju õrun rẹ̀, o si wipe, Emi o jade lọ bi ìgba iṣaju, ki emi ki o si gbọ̀n ara mi. On kò si mọ̀ pe OLUWA ti kuro lọdọ on.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun pè é wí pé, “Sámúsónì àwọn Fílístínì dé láti mú ọ.” Òun jí ní ojú oorun rẹ̀, ó sì sọ pé, “Èmi yóò jáde lọ bí í ti àtẹ̀yìn wá, kí èmi sì gba ara mi, kí n di òmìnira” Ṣùgbọ́n òun kò mọ̀ pé OLÚWA ti fi òun sílẹ̀.