Judges 16:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn eniyan rí i, wọ́n yin oriṣa wọn; wọ́n ní, “Oriṣa wa ti fi ọ̀tá wa lé wa lọ́wọ́, ẹni tí ó sọ ilẹ̀ wa di ahoro tí ó sì pa ọpọlọpọ ninu wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn enia si ri i, nwọn fi iyin fun oriṣa wọn: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi ọtá wa lé wa lọwọ, ẹniti npa ilẹ wa run, ti o si pa ọ̀pọlọpọ enia ninu wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ènìyàn rí Sámúsónì wọ́n yin ọlọ́run wọn wí pé, “Ọlọ́run wa ti fi ọ̀ta wa lé wa lọ́wọ́. Àní ẹni tí ó ti run ilẹ̀ wa ẹni tí ó ti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wa.”