Judges 16:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ilé náà kún fún ọpọlọpọ eniyan, lọkunrin ati lobinrin; gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ Filistini ni wọ́n wà níbẹ̀. Lórí òrùlé nìkan, àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀ tó ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan, lọkunrin ati lobinrin tí wọn ń wo Samsoni níbi tí ó ti ń dá wọn lára yá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ile na kún fun ọkunrin ati obinrin; gbogbo awọn ijoye Filistini si wà nibẹ̀; awọn ti o si wà lori orule, ati ọkunrin ati obinrin, o to ìwọn ẹgbẹdogun enia, ti nworan Samsoni nigbati o nṣiré.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àsìkò náà, tẹ́ḿpìlì yìí kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin; gbogbo àwọn ìjòyè Fílístínì wà níbẹ̀, ní ókè ilé náà, níbi tí ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3000) àwọ́n ọkùnrin àti obìnrin tí ń wòran Sámúsónì bí òun ti ń ṣeré.