Judges 16:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn Samsoni sùn títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ní òru náà, ó gbéra, ó gbá ìlẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà bodè ìlú náà mú ati àwọn òpó rẹ̀ mejeeji, ó sì fà á tu pẹlu irin ìdábùú rẹ̀, ó gbé wọn lé èjìká, ó sì rù wọ́n lọ sí orí òkè kan tí ó wà ní iwájú Heburoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samsoni si dubulẹ titi o fi di ãrin ọganjọ, o si dide lãrin ọganjọ, o si gbé ilẹkun-ibode ilu na, ati opó mejeji, o si fà wọn tu pẹlu idabu-ilẹ̀kùn, o gbé wọn lé ejika rẹ̀, o si rù wọn lọ si ori òke kan ti o wà niwaju Hebroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Sámúsónì sùn níbẹ̀ di àárin ọ̀gànjọ́ (èyí nì di agogo méjìlá òru). Òun sì dìde ní ọ̀gànjọ́, ó fi ọwọ́ di àwọn ìlẹ̀kùn odi ìlú náà mú, pẹ̀lú òpó méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu, pẹ̀lú ìdábú àti ohun gbogbo tí ó wà lára rẹ̀. Ó gbé wọn lé èjìká rẹ̀ òun sì gbé wọn lọ sí orí òkè tí ó kọjú sí Hébírónì.