Judges 16:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wí pé, “Jẹ́ kí èmi náà kú pẹlu àwọn ará Filistia.” Ó bá bẹ̀rẹ̀ pẹlu gbogbo agbára rẹ̀. Ilé náà sì wó lu gbogbo àwọn ọba Filistini ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ninu rẹ̀. Nítorí náà, iye eniyan tí ó pa nígbà tí òun náà yóo fi kú, ju àwọn tí ó pa nígbà tí ó wà láàyè lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Samsoni si wipe, Jẹ ki nkú pẹlu awọn Filistini. O si fi gbogbo agbara rẹ̀ bẹ̀rẹ; ile na si wó lù awọn ijoye wọnni, ati gbogbo enia ti o wà ninu rẹ̀. Bẹ̃li awọn okú ti o pa ni ikú rẹ̀, pọjù awọn ti o pa li ãyè rẹ̀ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sámúsónì sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi kú pẹ̀lú àwọn Fílístínì!” Òun sì fi agbára ńlá tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ilé náà wó lu àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. Báyìí ni ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbà ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ.