Judges 16:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ bá wá gbé òkú rẹ̀, wọ́n lọ sin ín sáàrin Sora ati Eṣitaolu ninu ibojì Manoa, baba rẹ̀. Ogún ọdún ni ó fi ṣe aṣiwaju ní Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn arakunrin rẹ̀ ati gbogbo idile baba rẹ̀ sọkalẹ wá, nwọn si gbé e gòke, nwọn si sin i lãrin Sora on Eṣtaolu ni ibojì Manoa baba rẹ̀. O si ṣe idajọ Israeli li ogún ọdún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rẹ̀ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀ ní àpapọ̀ gòkè lọ wọ́n sì gbé e, wọ́n gbé e padà wá, wọ́n sì sin ín sí agbede-méjì Sórà àti Ésítaólì sínú ibojì Mánóà baba rẹ̀. Òun ti ṣe àkóso Ísírẹ́lì ní ogún (20) ọdún.