Judges 17:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Wọ́n gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka mọ́ ọ lọ́wọ́ nígbà kan, mo sì gbọ́ tí ò ń gbé ẹni tí ó gbé owó náà ṣépè, ọwọ́ mi ni owó náà wà, èmi ni mo gbé e.” Ìyá rẹ̀ dá a lóhùn pé, “OLUWA yóo bukun ọ, ọmọ mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si wi fun iya rẹ̀ pe, Ẹdẹgbẹfa owo fadakà ti a kólọ lọwọ rẹ, nitori eyiti iwọ gegún, ti iwọ si sọ̀rọ rẹ̀ li etí mi pẹlu, kiyesi i, fadakà na wà li ọwọ́ mi; emi li o kó o. Iya rẹ̀ si wipe, Alabukún ti OLUWA ni ọmọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
sọ fún ìyá rẹ̀ pé, “Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà èyí tótó kílógírámù mẹ́talá tí wọ́n jí mọ́ ọ lọ́wọ́, àti nípa èyí tí mo gbọ́ tí ìwọ ń ṣépè (gégùn ún). Kíyèsi fàdákà náà wà ní ọ̀dọ̀ mi, èmi ni mo kó o.” Nígbà náà ni ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Kí OLÚWA bùkún ọ ọmọ mi!”