Judges 17:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mika gbé ẹẹdẹgbẹfa (1,100) owó fadaka náà pada fún ìyá rẹ̀. Ìyá rẹ̀ bá dáhùn pé, “Mo ya fadaka náà sí mímọ́ fún OLUWA, kí ọmọ mi yá ère fínfín kan kí ó sì yọ́ fadaka náà lé e lórí. Nítorí náà, n óo dá a pada fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si kó ẹdẹgbẹfa owo fadakà na fun iya rẹ̀ pada, iya rẹ̀ si wipe, Patapata ni mo yà fadakà wọnni sọ̀tọ fun OLUWA kuro li ọwọ́ mi, fun ọmọ mi, lati fi ṣe ere fifin ati ere didà: njẹ nitorina emi o fun ọ pada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó da ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà ṣékélì fàdákà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ dáhùn pé, “Èmi ti fi òtítọ́ inú ya sílífà náà sọ́tọ̀ sí OLÚWA fún ọmọ mi láti fi dá ère dídá àti ère gbígbẹ́. Èmi yóò dá a padà fún ọ.”