Judges 17:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Mika kó owó náà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ mú igba owó fadaka ninu rẹ̀, ó kó o fún alágbẹ̀dẹ fadaka láti yọ́ ọ sórí ère náà, wọ́n sì gbé ère náà sí ilé Mika.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn o kó owo na pada fun iya rẹ̀; iya rẹ̀ si mú igba owo fadakà, o si fi i fun oniṣọnà, ẹniti o fi i ṣe ere fifin ati ere didà: o si wà ni ile Mika.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà òun dá sílífà náà padà fún ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì mú igba (200) ṣékélì fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà ẹni tí ó fi wọ́n rọ ère fínfín àti ère dídà. Wọ́n sì kó wọn sí ilé Míkà.