Judges 17:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọdọmọkunrin náà kó kúrò ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda, láti lọ máa gbé ibikíbi tí ó bá ti rí ààyè. Bí ó ti ń lọ, ó dé ilé Mika ní agbègbè olókè ti Efuraimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin na si ti ilu Beti-lehemu-juda lọ, lati ṣe atipo nibikibi ti o ba ri: on si dé ilẹ òke Efraimu si ile Mika, bi o ti nlọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
fi ìlú náà sílẹ̀ láti wá ibòmíràn láti máa gbé. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Míkà nínú àwọn ilẹ̀ òkè Éfúráímù.