Judges 18:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò kan, kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli, ati pé, ní àkókò náà, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tí wọn yóo gbà, tí wọn yóo sì máa gbé, nítorí pé, títí di àkókò yìí wọn kò tíì fún wọn ní ilẹ̀ kankan láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LI ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: ati li ọjọ́ wọnni ẹ̀ya Dani nwá ilẹ-iní kan lati joko si; nitoripe titi o fi di ọjọ́ na, ilẹ-iní wọn lãrin awọn ẹ̀ya Israeli kò ti ibọ́ si ọwọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní ọba. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ẹ̀yà Dánì ń wá ilẹ̀ ti wọn, níbi tí wọn yóò máa gbé, nítorí pé títí di àkókò náà wọn kò ì tí ì pín ogún ilẹ̀ fún wọn ní ìní láàárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.