Judges 18:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ bá lọ, ẹ óo dé ibìkan tí àwọn eniyan ń gbé láìbẹ̀rù, ilẹ̀ náà tẹ́jú. Dájúdájú Ọlọrun ti fi lé yín lọ́wọ́, kò sí ohun tí eniyan ń fẹ́ ní ayé yìí tí kò sí níbẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ẹnyin ba lọ, ẹnyin o dé ọdọ awọn enia ti o wà laibẹ̀ru, ilẹ na si tobi: nitoriti Ọlọrun ti fi i lé nyin lọwọ; ibiti kò sí ainí ohunkohun ti mbẹ lori ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ ó ò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.”