Judges 18:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni àwọn ọkunrin marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ Laiṣi sọ fún àwọn arakunrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ̀wù efodu kan wà ninu àwọn ilé wọnyi ati àwọn ère kéékèèké, ati ère tí wọ́n gbẹ́ tí wọ́n sì yọ́ fadaka bò lórí, nítorí náà, kí ni ẹ rò pé ó yẹ kí á ṣe?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn ọkunrin marun ti a rán ti o ti lọ ṣe amí ilẹ Laiṣi dahùn, nwọn si wi fun awọn arakunrin wọn pe, Ẹ mọ̀ pe efodu kan wà ninu ile wọnyi, ati terafimu, ati ere fifin, ati ere didà? njẹ nitorina ẹ rò eyiti ẹnyin o ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Láìsì wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní èwù Éfódì, àwọn yóòkù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.”