Judges 18:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn marun-un tí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà bá wọlé, wọ́n gbé ère dídà, wọn mú ẹ̀wù efodu, wọ́n sì kó àwọn ère kéékèèké ati ère fínfín. Ọdọmọkunrin alufaa yìí sì wà ní ẹnu ibodè pẹlu àwọn ẹgbẹta (600) ọkunrin láti inú ẹ̀yà Dani tí wọ́n ti dira ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin marun ti o ti lọ iṣe amí ilẹ na gòke lọ, nwọn si wá si ibẹ̀ na, nwọn si kó ere fifin, ati efodu, ati terafimu, ati ere didà na: alufa na si duro li ẹnu-ọ̀na pẹlu awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, éfódì náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní àbáwọ ẹnu odi náà.