Judges 18:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́, pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì tẹ̀lé wa, kí o jẹ́ baba ati alufaa fún wa. Èwo ni ìwọ náà rò pé ó dára jù; kí o jẹ́ alufaa fún ilé ẹnìkan ni tabi fún odidi ẹ̀yà kan ati ìdílé kan ní Israẹli?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun u pe, Dakẹ, fi ọwọ́ rẹ lé ẹnu rẹ, ki o si ma bá wa lọ, ki o si ma ṣe baba fun wa ati alufa: o ha san fun ọ lati ṣe alufa fun ile ọkunrin kan, tabi ki iwọ ki o ṣe alufa fun ẹ̀ya ati idile kan ni Israeli?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Ísírẹ́lì bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?”