Judges 18:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, àwọn ẹ̀yà Dani rán akikanju marun-un láàrin àwọn eniyan wọn, láti ìlú Sora ati Eṣitaolu, kí wọ́n lọ ṣe amí ilẹ̀ náà kí wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n wí fún àwọn amí náà pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì yẹ ilẹ̀ náà wò.” Wọ́n bá gbéra, wọ́n lọ sí agbègbè olókè ti Efuraimu. Nígbà tí wọ́n dé ilé Mika, wọ́n wọ̀ sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Dani si rán ọkunrin marun ninu idile wọn lati àgbegbe wọn wá, awọn ọkunrin alagbara, lati Sora, ati Eṣtaolu lọ, lati lọ ṣe amí ilẹ na, ati lati rìn i wò; nwọn si wi fun wọn pe, Ẹ lọ rìn ilẹ na wò: nwọn si dé ilẹ òke Efraimu, si ile Mika, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Dánì rán àwọn jagunjagun márùn ún lọ láti Ṣórà àti Ésítaólì láti yọ́ ilẹ̀ náà wò àti láti rìn ín wò. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ojú fún gbogbo àwọn ẹ̀yà wọn. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ rin ilẹ̀ náà ká, kí ẹ sì wò ó fínnífínní.” Àwọn ọkùnrin náà wọ àwọn ìlú tí ó wà ní agbégbé òkè Éfúráímù, wọ́n sì dé ilé Míkà, níbi tí wọ́n sùn ní òru náà.