Judges 18:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí àwọn ará Dani ti kó oriṣa Mika, tí wọ́n sì ti gba alufaa rẹ̀, wọ́n lọ sí Laiṣi, wọ́n gbógun ti àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n jókòó sí jẹ́jẹ́ láì bẹ̀rù; wọ́n pa wọ́n, wọ́n sì dáná sun ìlú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kó awọn nkan wọnni ti Mika ṣe, ati alufa ti o ní, nwọn si wá si Laiṣi sọdọ awọn enia ti o wà ni ijokojẹ ati laibẹ̀ru, nwọn si fi oju idà kọlù wọn, nwọn si fi iná kun ilu na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì kó àwọn ohun tí Míkà ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí Láísì, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run.