Judges 18:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà wọ́n sílẹ̀, nítorí pé wọ́n jìnnà sí ìlú Sidoni, wọn kò sì bá ẹnikẹ́ni ní àyíká wọn da nǹkankan pọ̀. Àfonífojì Betirehobu ni ìlú Laiṣi yìí wà. Wọ́n tún un kọ́, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kò si sí olugbala, nitoriti o jìna si Sidoni, nwọn kò si bá ẹnikẹni ṣe; o si wà ni afonifoji ti o wà ni Beti-rehobu. Nwọn si kọ́ ilu na, nwọn si ngbé inu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará Ṣídónì, wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bá a Bẹti-Réhóbù. Àwọn ará Dánì sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀.