Judges 18:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n yí orúkọ ìlú náà pada kúrò ní Laiṣi tí ó ń jẹ́ tẹ́lẹ̀, wọ́n sọ ọ́ ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si pè orukọ ilu na ni Dani, gẹgẹ bi orukọ Dani baba wọn, ẹniti a bi fun Israeli: ṣugbọn Laiṣi li orukọ ilu na li atijọ rí.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní Dánì gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn Dánì, ẹni tí wọ́n bí fún Ísírẹ́lì: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Láísì ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí.