Judges 18:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n wà ní ilé Mika, wọ́n ṣàkíyèsí bí ọdọmọkunrin tí ó wà ní ilé Mika ṣe ń sọ̀rọ̀, wọ́n sì mọ̀ pé ọmọ Lefi ni. Wọ́n bá bi í pé, “Ta ló mú ọ wá síhìn-ín? Kí ni ò ń ṣe níhìn-ín? Kí sì ni iṣẹ́ rẹ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn wà leti ile Mika, nwọn si mọ̀ ohùn ọmọkunrin Lefi na: nwọn si wọ̀ inu ile na, nwọn si wi fun u pe, Tali o mú ọ wá ihinyi? kini iwọ si nṣe ni ihinyi? kini iwọ si ní nihin?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ tòsí ilé e Míkà, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́mọkùnrin Léfì náà mọ̀, torí náà wọ́n yípadà, wọ́n sì wọ inú ilé náà lọ wọ́n sì bi í pé, “Tá ni ó mú ọ wa sí ibi? Kí ni ìwọ ń ṣe níhìnìnyìí? Èéṣe tí o fi wà ní ibí?”