Judges 18:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ará Dani gbé ère dídà náà kalẹ̀ fún ara wọn. Jonatani ọmọ Geriṣomu, ọmọ Mose ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni wọ́n jẹ́ alufaa fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí wọ́n kó gbogbo agbègbè wọn ní ìgbèkùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Dani si gbé ere fifin na kalẹ: ati Jonatani, ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, on ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin li o nṣe alufa fun ẹ̀ya Dani titi o fi di ọjọ́ ti a fi kó ilẹ na ni igbekun lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Dánì sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀; Jónátanì ọmọ Gáṣómì, ọmọ Móṣè, àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà Dánì títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbékùn.